IFIHAN 7:9-17
AWON TI O FO ASO WON
IFIHAN 7:9-17
ÌFIHÀN 7:9 LEHIN NA, MO RI, SI KIYESI I, ỌPỌLỌPỌ ENIA TI ENIKENI KÒ LE KÀ, LATI INU ORILE-ÈDE GBOGBO, ATI EYA, ATI ENIA, ATI LATI INU ÈDE GBOGBO WÁ, NWỌN DURO NIWAJU ITE, ATI NIWAJU ỌDỌ-AGUTAN NA, A Wọ̀ WỌN LI ASỌ FUNFUN, IMỌ-ỌPE SI MBE LI ỌWỌ WỌN; 10 NWỌN SI KIGBE LI OHÙN RARA, WIPE, IGBALA NI TI ỌLỌRUN WA TI O JOKO LORI ITE, ATI TI ỌDỌ-AGUTAN. 11 GBOGBO AWỌN ANGELI SI DURO YI ITẹ́ NA KÁ, ATI YI AWỌN ÀGBA ATI AWỌN EDA ALÃYE MERIN NA KÁ, NWỌN WOLE NWỌN SI DOJUBOLE NIWAJU ITE NA NWỌN SI SÌN ỌLỌRUN, 12 WIPE, AMIN: IBUKÚN, ATI OGO, ATI ỌGBỌN, ATI ỌPE, ATI AGBARA, ATI IPÁ FUN ỌLỌRUN WA LAI ATI LAILAI. AMIN. 13 ỌKAN NINU AWỌN ÀGBA NA SI DAHÙN, O BI MI PE, TALI AWỌN WỌNYI TI A WỌ LI ASỌ FUNFUN NÌ? NIBO NI NWỌN SI TI WÁ?
14 MO SI WI FUN U PE, OLUWA MI, IWỌ LI O LE MỌ. O SI WI FUN MI PE, AWỌN WỌNYI LI O JADE LATI INU IPỌNJU NLA, NWỌN SI FỌ ASỌ WỌN, NWỌN SI SỌ WỌN DI FUNFUN NINU EJE ỌDỌ-AGUTAN NA. 15 NITORINA NI NWỌN SE MBE NIWAJU ITE ỌLỌRUN, TI NWỌN SI NSÌN I LI ỌSÁN ATI LI ORU NINU TEMPILI RE: ENITI O JOKO LORI ITE NA YIO SI SIJI BÒ WỌN. 16 EBI KÌ YIO PA WỌN MỌ, BEELI ONGBE KÌ YIO GBE WỌN MỌ; BEELI ÕRÙN KÌ YIO PA WỌN TABI ÕRUKÕRU. 17 NITORI ỌDỌ-AGUTAN TI MBE LI ARIN ITE NA NI YIO MÃ SE OLUSỌ-AGUTAN WỌN, TI YIO SI MÃ SE AMỌNA WỌN SI IBI ORISUN OMI IYÈ: ỌLỌRUN YIO SI NÙ OMIJE GBOGBO NÙ KURO LI OJU WỌN.
I PETERU 1:15 SUGBON GEGE BI ENI TI O PE NYIN TI JE MIMO, BEENI KI ENYIN NA SI JE MIMO NINU IWA NYIN GBOGBO.
KINI ASO?
ASO JE OHUN TI A NGBE WO TI AWON ENIYAN FI NDA WA MO.
ASO JE OHUN TI O WA LODE ARA TI ARAYE NRI TI WON SI NWO.
ASO JE OHUN TI A NGBE WO TI O SI NSO OHUN PUPO NIPA AYE WA.
BI ASO BA MO, ENITO WO O YIO JE ITEWOGBA LAWUJO, SUGBON BI ASO BA DOTI YIO MU EGAN ATI ABUKU BA ENI TI O WO O, KO SI NI RORUN FUN UN LATI DURO DEEDEE LAWUJO.
NIPA TI EMI,
ASO NSAPEERE IWA ATI ISE WA LAARIN AYE.
ASO NSAPEERE IGBEAYE WA LAPAPO.
A NI LATI FO ASO WA KI O MO. AWON ENIYAN TI A KA NIPA WON NINU IFIHAN 7:9, 14 FO ASO WON NINU EJE ODO AGUNTAN, EYI TI O TUMO SI WIPE WON DI ATUNBI NIPA EJE JESU, WON SI NGBE IGBE AYE MIMO NIPASE OORE OFE EJE NAA.
PUPO ENIYAN TI O NTELE KRISTI LONI NI IGBEAYE WON KUN FUN GEDEGEDE ESE; KEFERI PONBELE SAN JU ELOMIRAN NINU IJO LONI.
KINI FIFO ASO TUMO SI?
O TUMO SI DIDI ATUNBI LOJULOWO ATI GBIGBE NINU IWA MIMO – EFESU 4:21-24; KOLOSSE 3:5-10.
O TUMO SI SISE ATUNSE IGBEAYE RE ATI IWA RE – EFESU 5:1-5; I PETERU 2:11-12.
O TUMO SI MI MU GBOGBO EERI ESE KURO NINU AYE RE – II TIMOTEU 2:21-22; KOLOSSE 1:21, 27; II KORINTI 7:11.
O TUMO SI JIJOWO NINU OHUN TO NSE TO LODI SI IWA-BI-OLORUN – I TIMOTEU 6:6.
O TUMO SI YIYE ISE OWO RE WO LOJOOJUMO ATI SISE ATUNSE TO YE – FILIPPI 2:12-15; GALATIA 6:4-5.
O TUMO SI YIYERA FUN EGBEKEGBE, OREKORE ATI IBASEPO TO TIMO SI ESE NINU OKUNKUN ATI NI GBANGBA – EFESU 5:11-12.
O TUMO SI SISA FUN GBOGBO IFEKUFE ESE ATI GBOGBO ONFA IBI – I TESSALONIKA 5:22-24.
O TUMO SI IPINNU LATI MASE PADA SINU EEBI RE ATIJO – I KORINTI 6:9-11; II PETERU 2:20-22.
O TUMO SI KIKO LATI FI ARA RE FUN FAAJI ATI AYE JIJE – I TIMOTEU 5:6.
O TUMO SI WIWADI ARA RE LOJOOJUMO LATI NI IDANILOJU WIPE O DURO GBOINGBOIN NINU IGBAGBO, OTITO ATI IHINRERE – II KORINTI 13:5.
O TUMO SI TITERI IFE RE BA FUN IFE OLORUN NINU OHUN GBOGBO YALA O RORUN TABI KO RORUN – JAKOBU 4:7.
O TUMO SI YIYERA FUN ASILO AHON – EFESU 4:29; JAKOBU 1:26; MATTEU 12:33-37.
O TUMO SI SISE ILAJA ATI GBIGBE NI ALAAFIA PELU GBOGBO ENIYAN – HEBERU 12:14.
O TUMO SI RIRONU AWON NKAN TORUN TO GAJU TAYE LO – KOLOSSE 3:1-2
O TUMO SI DIDEKUN LATI MAA GBE IGBEAYE RE NI AWOKOSE AWON KEFERI – EFESU 4:17-20; FILIPPI 2:27.
O TUMO SI SISORA KI A MA BAA JE OHUN IKOSE FUN AWON ELOMIRAN – I KORINTI 8:9.
O TUMO SI MIMU ARA RE WA SABE ITELORIBA KI O MA BAA DI ENI ITANU NIKEHIN – I KORINTI 9:27.
O TUMO SI SISA FUN AJOPIN PELU AWON EMI ESU – II KORINTI 10:20-21.
O TUMO SI SISE OHUN TO WU OLUWA NI GBOGBO IGBA DIPO TITE ENIYAN TABI ARA LORUN – ROMU 8:8.
O TUMO SI JIJE APEERE ISE RERE TI ARAYE KO LEE RI ARIWISI OHUN BUBURU SI – TITU 2:7-8.
O TUMO SI SISA FUN IFEKUFE ATI AISODODO GBOGBO – GALATIA 5:24; II TIMOTEU 2:19-22.
IKADI: GBIGBE NI AFIJO KRISTI NINU AYE IDIBAJE ATI ESE YI NBEERE PE KI A MAA FO ASO WA LOJOOJUMO KI EGBIN AYE MA BAA TA BA ORUKO MIMO JESU.A TI KIYESI OHUN TI O TUMO SI LATI FO ASO WA; LEREFE, O TUMO SI KI A GBE IGBEAYE MIMO TI YIO LE KAWA YE FÜR ILE OGO NI AYERAYE – IFIHAN 22:13-15.
AYE YI KUN FUN EGBIN ESE LONIRUURU, SUGBON OLORUN NPE WA LATI YA ARA WA SOTO ATI LATI YA ARA WA SI MIMO KI A MA BAA SEGBE PELU AYE ESE YI – JOBU 11:14; I KORINTI 5:7-11; 6:9-11; II PETERU 3:11-14; IFIHAN 21:27.
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 9:8 JE KI ASO RE KI O MA FUN NIGBAGBOGBO; KI O MA SI JE KI ORI RE KI O SE ALAINI ORORO IKUNRA.
KOKO ADURA: ASO MI A FUNFUN, LAU, LAULAU, AISEDEEDE MI A KURO MA FUNFUN, ESE MI A PARE O BI EGBON OWU.
OLUWA RANMILOWO LATI MAA KIYESARA LOJOOJUMO NINU IGBESE MI GBOGBO LORÚKO JÉSÙ.
BABA AGBA, FI OPO OORE OFE FUN MI LATI MAA FO ASO MI LOJOOJUMO LORÚKO JÉSÙ.
IGBEAYE MI MAJE O DOORUN PA O MO LORÚKO JÉSÙ.